ÀGBÉYẸ̀WÒ ÌWÉ ÌTÀN-ÀRÒSỌ ṢE BÓO TI MỌ
Abstract
Gẹ́gẹ́ bí i lámèyítọ́, dandan ni láti ṣe ìdájọ́ lórí iṣẹ́ yálà iṣẹ́ náà dára tàbí ó kùdíẹ̀ káàtó. Kọ́láwọlé Adéyẹmọ gbìyànjú lórí ìwé ìtàn-àròsọ rẹ̀ Ṣe Bóo Ti Mọ tí a túpalẹ̀ yìí. Òǹkọ̀wé gbé ìtàn rẹ̀ náà ka ìfẹ́ owó tí ó jẹ mọ́ ìṣẹ̀lẹ̀ àwùjọ tí a kò lè fi ojú bíńtí wò nítorí ó fẹ́ fi ipin ojú àwùjọ han àwùjọ.
Ó hàn gbangba pé ojúlówó ọmọ Yorùbá ni òǹkọ̀wé nítorí ìṣọwọlo-èdè rẹ̀. Ó gbọ́ èdè Yorùbá dáadáa, ó sì lo èdè nínú iṣẹ́-ọnà rẹ̀ ní ọ̀nà tí ó gbé ẹwà èdè jáde. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìlò-èdè àti ọnà-èdè ló jẹyọ. Yàtọ̀ sí èyí, àhunpọ̀-ìtàn náà lọ tààrà kò ta kókó, ẹnikẹ́ni tó bá mú ìwé náà lè kà á ní àkàgbádùn àti ní ìrọ̀rùn nítorí ìlò-èdè inú rẹ̀ kó lọ́júpọ̀ rárá.
Yorùbá bọ̀ wọ́n ní “a kò lè rìn kórí mámì” bí iṣẹ́ yìí ti dára tó, a rí àwọn kùdìẹ̀ kudiẹ níbẹ̀, èyí tí a ṣe àkíyèsí pé, ó ti ọwọ́ atẹ̀wétà jáde. Àwọn àṣìtẹ̀ nínú ìwé ìtàn-àròsọ Ṣe Bóo Ti Mọ ni.
Orí kìnín-ní (o.i 5) àmì ohùn ìsàlẹ̀ ló yẹ kí ó wà lórí ‘ìyà’ dípò àmì ohùn ìsàlẹ̀ àti òkè ‘ìyá’
Orí kìn-ín-ní (o.i 13) níbi tí wọ́n ti kọ ‘ṣíṣẹ̀’ kò yẹ kí wọ́n yán ‘s’ méjèèjì nídìí, àkọ́kọ́ nìkan ló yẹ kí wọ́n yán nídìí ‘ṣísẹ̀’.
Orí kejì (o.i 29) àmì ohùn ìsàlẹ̀ àti òkè ló yẹ kó wà ‘ìyá’ dípò àmì ìsàlẹ̀ ‘ìyá’
Ní orí kẹta (o.i 47) tí wọ́n ti kọ ‘Tẹjúmádé’ dípò ‘Tẹjúmọ́lá’
Orí karùn-ún (o.i 69) tí wọ́n ti kọ ‘másosẹ̀’, ‘márosẹ̀’ ló yẹ kí wọ́n kọ.
Orí kẹfà (o.i 90) tí wọ́n ti kọ ‘Adéraní’ ‘Adérántí’ ló yẹ kó wà níbẹ̀.
Àwọn àṣìṣe aṣèwétà yìí ni a rí tí a sì ṣe àtúnṣe rẹ̀ nínú ìwádìí náà.
Full-Text Access Notice
In accordance with the NERD Policy on promoting peer-reviewed publication, public access to the full text of a project, thesis or dissertation is restricted for three years, allowing the author and supervisors sufficient time to pursue peer-reviewed publication.
During this period, researchers with legitimate academic or research purposes may request authorisation directly from the author to enable NERD to release the indexed full texts of the work using the form below.