ÀGBÉYẸ̀WÒ EWÌ ALOHÙN YORÙBÁ GẸ́GẸ́ BÍ ÈRÒJÀ ÀWỌN ORIN HÁRÚNÀ ÌS̩Ò̩LÁ
Abstract
ÀS̩AMÒ̩
Orís̩ìírís̩ìí ò̩nà ni Yorùbá ń gbà gbé èrò wo̩n jáde fún aráyé gbó̩̩, ò̩kan pàtàkì lára àwo̩n ò̩nà náà ni orin jé̩̩. Pàtàkì ni orin nínú ìgbésí ayé o̩mo̩ ènìyàn, ó lè jé̩̩ orin ìdùnnú tàbí ìbànújé̩̩. Ò̩kan pàtàkí lára ìsò̩rí lítíres̩ò̩ ni ewí jé̩̩. Lára ìsò̩rí mé̩̩ta tí ewì pín sí yìí ni a ti rí orin. A lè so̩ pé orin jé̩̩ ara às̩à àti ìs̩è̩s̩e Yorùbá, o máa ń wáyé nínú ìs̩è̩lè̩ ojoojúmó̩̩. Ohun tí ó je̩ wá lógún nínú is̩é̩̩ ìwádìí yìí ni ò̩nà tí Hárúna Ìs̩ò̩lá gbà lo èdè pàápàá àwo̩n èròjà àbáláyé e̩nu Yorùbá. Èro wa ni láti wo àwon ìlò-èdè yìí láwòjinlè̩. Èròńgbà ìwádìí yìí ni láti s̩e àgbéyè̩wò ewì alohùn Yorùbá gé̩̩gé̩̩ bí èròjà àwo̩n orin Hárúnà Ìsò̩lá láti gbé ò̩ko̩rin yìí sí ìpó pàtàkì nínú àwo̩n tí wó̩̩n ń fi orin s̩e àgbéjáde àwo̩n ìs̩è̩lè̩ àwùjo̩. Èrèdí is̩é̩̩ ìwádìí ni láti wo kókó-ọ̀rọ̀, bátànì, akópa àti ìlò- èdè inú orin Hárúnà Ìsò̩lá. O̩gbó̩̩n ìs̩è̩wádìí tí a s̩àmúlò ni sís̩e àgbéyè̩wò is̩é̩̩ àwo̩n onímò̩ ìs̩ájú lórí orin Hárúna Ìs̩ò̩lá àti lórí orin ni lápapọ̀, a sì s̩e àgbéyè̩wò àwo̩n àwo orin Hárúna Ìs̩ò̩lá kan. Tíó̩̩rì Ìfojú-Ìmò̩-ìbágbépò̩-àwùjo̩-wo-is̩é̩̩ lítírés̩ò̩ ni a sàmúlo. Ohun tí tíó̩rì yìí fún-ìka-mó̩ ni àjo̩s̩epò̩ tó dán mó̩rán tó wà láàárín àwùjo̩ àti lítírés̩ò̩, èyí túmò̩ sí pé èrò tí ò̩ko̩rin ń gbé jáde nínú orin rè̩ kì í s̩e tirè̩ nìkan, bí kò s̩e láti inú ìs̩è̩lè̩, ìrírí àti ìgbàgbó̩̩ àwùjọ. Àbájáde ìwádìí yìí fi hàn pé, àká òwe ni orin Hárúnà Ìs̩ò̩lá jé̩̩, ó fé̩̩ràn láti máa pa òwe púpò̩ débi pé, tíràkì kan nínú ò̩kan nínú àwo̩n àwo rè̩ tí ó pe àko̩lé rè̩ ní ‘iná ràn’ jé̩̩ kìkìdá òwé. Kì í s̩e òwe nìkan, títí dé orí lílo àwo̩n ò̩rò̩ àbáláyé e̩nu Yorùbá bí i ìwúre, o̩fò̩, orin, oríkì àti àwo̩n o̩nà-èdè bí i; àfiwé, ìfò̩rò̩dárà, àwítúnwí, ìbádó̩̩gba gbólóhùn, ìfohunpènìyàn ìfènìyàpohun àti bé̩̩è̩ bé̩̩è̩ lo̩. Orin Hárúnà Ìs̩ò̩lá jé̩̩ ilé ìs̩úra o̩gbó̩̩n, ìs̩ítí, ìkìlò̩, ìmò̩ràn, ìyànjú, ìdárayá, ìtó̩̩só̩̩nà, àti àwo̩n ìs̩è̩lè̩ àwùjo̩ mìíràn. Bákan náà àwo̩n òǹkàwé yóò le mó̩̩ ìdí abájó̩̩ tí Hárúna Ìs̩ò̩lá fi jé̩̩ ò̩kan pàtàkì láàárín àwo̩n ò̩ko̩rin àpàlà ní ilẹ̀ Yorùbá
Full-Text Access Notice
In accordance with the NERD Policy on promoting peer-reviewed publication, public access to the full text of a project, thesis or dissertation is restricted for three years, allowing the author and supervisors sufficient time to pursue peer-reviewed publication.
During this period, researchers with legitimate academic or research purposes may request authorisation directly from the author to enable NERD to release the indexed full texts of the work using the form below.