ÌTÚPALẸ̀ ÌWÉ ÌTÀN-ÀRÒSỌ TA Ń LỌMỌ TÍ DIÍPỌ̀ GBÉNRÓ KỌ
Abstract
Kíkọ ìwé ìtàn-àròsọ jẹ́ ọ̀kan pàtàkì lára àwọn iṣẹ́ ọnà aláwòmọ́ lítíréṣọ̀ tí àwọn onímọ̀ àti àwọn oníṣẹ́ lámèyítọ́ kó kọyán rẹ̀ kéré rárá. Àwọn òǹkọ̀wé ìwé ìtàn-àròsọ sì pọ̀ níye tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tó fi jẹ́ pé, ìwé ìtàn-àròsọ tó wà lórí àtẹ lónìí kò fi lóńkà mọ́. Bí àwọn ọkùnrin ti ń kọ lóríṣiríṣi náà ni àwọn obìnrin ń kọ. Kódà, àwọn tí kò kẹ́kọ̀ọ́ rárá nípa èdè Yorùbá tó jẹ́ pé, ọ̀tọ̀ ni ohun tí wọ́n kẹ́kọ̀ọ́ nípa rẹ̀ náà kò gbẹ́yìn nínú à ń kọ ìwé ìtàn-àròsọ. Èyí sì wáyé nítorí ìfẹ́ tí àwọn wọ̀nyẹn ní sí èdè Yorùbá, pàápàá jùlọ láti gbé àṣà àti ìṣe Yorùbá lárugẹ. Èyí sì ń mú ìdàgbàsókè dé bá ìwé ìtàn-àròsọ kíkọ àti ìsọ̀rí àwọn iṣẹ́ ọnà aláwòmọ́ lítíréṣọ̀ yòókú.
Iṣẹ́ ìtúpalẹ̀ ìwé ìtàn-àròsọ Ta ń lọmọ ti Diípọ̀ Gbénró kọ ni iṣẹ́ ìwádìí yìí dálé lórí. Ète wa lórí ìṣẹ́ yìí sì ni láti wá fìn-ín ìdí kókò nípa gbogbo ohun tó ṣodo sínú ìwé náà, pàápàá jùlọ láti ṣàwárí àwọn ẹ̀kọ́ tí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ inú ìwé náà kọ́ni.
Ní orí kìn-ìn-ní ni a ti máa ṣe ìfáàrà sí iṣẹ́ ìwádìí yìí níbi tí a ti máa sọ èròńgbà wa lórí iṣẹ́ náà tí ń ṣe ìdí kan pàtàkì tí a fi yan ìwè náà láàyò láti ṣiṣẹ́ ìwádìí lé lórí. A máa wo ibi tí iṣẹ́ ìwádìí náà yóò fẹjú dé, ọgbọ́n ìwádí tí a ṣàmúlò rẹ̀, ọ̀kan-ò-jọ̀kan àwọn ìpènijà tí a dojú kọ nínú iṣẹ́ ìwádìí náà àti àwọn àǹfààní ti iṣẹ́ náà yóò mú jáde láti fi kásẹ̀ orí náà nílẹ̀.
Full-Text Access Notice
In accordance with the NERD Policy on promoting peer-reviewed publication, public access to the full text of a project, thesis or dissertation is restricted for three years, allowing the author and supervisors sufficient time to pursue peer-reviewed publication.
During this period, researchers with legitimate academic or research purposes may request authorisation directly from the author to enable NERD to release the indexed full texts of the work using the form below.