ÀGBÉYẸ̀WÒ ỌDÚN ỌLỌ́FIN NÍ ÌLÚ ÌJÀRẸ́
Abstract
Oríṣiríṣi ọ̀nà ni ọdún ìbílẹ̀ pín sí láàárín àwọn Yorùbá, bí wọ́n ti ní èyí tí ó mú ìbọ dání ni ó jẹ́ pé, ayẹyẹ lásán ni àwọn mìíràn wà fún láti kó ara wọn jọ kí wọ́n sì ṣe wẹ̀jẹ wẹ̀mu. Bí àwọn ọdún ìbílẹ̀ ṣe wà káàkiri ìlú ni ṣíṣe wọn láti ìlú sí ìlú náà yàtọ̀ sí ara wọn. Ọ̀pọ̀ ọdún ló lè fi orúkọ jọra láàárín ìlú kan sí èkejì, àmọ́ tí ṣíṣe wọn yóò yàtọ̀ sí ara wọn, yàtọ̀ sí ọdún ìjẹṣu tó wọ́pọ̀ láàárín àwọn Àkókó tó jẹ́ pé, bákan náà ni ṣíṣe wọn káàkiri, àfi èyí tí wọ́n bá fúnra wọn so mọ́ ọdún mìíràn ni ṣíṣe rẹ̀ le yàtọ̀.
Nínú iṣẹ́ ìwádìí yìí, ọdún Ọlọ́fin ní ìlú Ìjàrẹ́ ni iṣẹ́ ìwádìí wa yìí dálé lórí. Òdú sì ni ọdún Ọlọ́fin yìí ni ìlú Ìjàrẹ́ láàárín àwọn ìlú tó wà ní ìpínlẹ̀ Oǹdó kì í ṣàìmọ̀ fólóko. Èyí fi hàn pé, ọdún Ọlọ́fin kì í ṣe àjèjì ọdún, ọdún tí ó ti wà nílẹ̀ tipẹ́ ni.
ÈRÒŃGBÀ IṢẸ́ ÌWÁDÌÍ
Yorùbá bọ̀, wọ́n ní, bí kò bá nídìí, obìnrin kì í jẹ́ Kúmólú, bí ó bá rí bẹ́ẹ̀, a jẹ pé, ikú ti pakin nínú ilé wọn ni. Ohun tí òwe yìí ń sọ fún wa ni pé, a kò lè dédé dáwọ́ lé irú iṣẹ́ báyìí láìní ìdí kan pàtàkì tí a fi fẹ́ ṣe iṣẹ́ náà tàbí ni ohun kan tí a fẹ́ fàyọ tàbí ní ohun kan pàtàkì tí a fẹ́ kí àwọn ènìyàn ó ní òye rẹ̀.
Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún ìbílẹ̀ ló wà káàkiri ilẹ̀ Yorùbá ti a le ṣiṣẹ́ lé lórí, ṣùgbọ́n ọdún Ọlọ́fin ní ìlú Ìjàrẹ́ ni a yàn láàyò. Èrèdí yíyan ọdún yìí ni láti mú ìtànkálẹ̀ dé bá ọdún yìí láàárín àwọn ọdún ìbílẹ̀ tó wà káàkiri, kí àwọn ènìyàn lè mọ̀ nípa ọdún náà nílé, lóko àti lẹ̀yìn odi. Òótọ́ ni pé, wọ́n ń ṣe ọdún yìí lóòrè-kóòrè, àmọ́ èyí kò lè fọn rere rẹ̀ nítorí kò sí àkọsílẹ̀ kankan tí a lè tọ́ka sí lórí rẹ̀. Ìdí nìyí tí a fi gbé ọdún yìí yẹ̀wò kí àwọn ènìyàn, yàtọ̀ sí àwọn ọmọ ìlú yìí lè rí i kà. Ó ṣe é ṣe kí a ti rí ẹni tó ti ṣe iṣẹ́ ìwádìí lórí ọdún yìí sẹ́yìn rí, pàápàá jù lọ fún iṣẹ́ àpilẹ̀kọ, àmọ́ àwa kò tí ì mọ ẹnikẹ́ni tó ti ṣe irú èyí rí. Èyí ló mú kí a yan iṣẹ́ yìí.
Èròńgbà wa mìíràn tún ni pé, iṣẹ́ ìwádìí yìí yóò tún fi kún ìmọ̀ tèmi alára láti lè mọ àwọn ohun tí a kò mọ̀ tẹ́lẹ̀ tàbí tí a kò gbọ́ rí nítorí oríṣiríṣi ìtàn ni a gbọ́ nígbà tí à ń ṣe ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò pẹ̀lú àwọn abẹ̀nà ìmọ̀ tí ẹnu sì yà wá láti gbọ́ irú àwọn ìtàn bẹ́ẹ̀.
IBI TÍ IṢẸ́ YÓÒ FẸJÚ DÉ
Ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ ohun ni a máa mẹ́nu bà nínú iṣẹ́ ìwádìí yìí, bẹ̀rẹ̀ láti orí ìtàn ìlú yìí títí dé orí ohun tó kéré jù lọ láti mọ̀ nípa ọdún Ọlọ́fin yìí. Gbogbo àwọn nǹkan tí a sì máa mẹ́nu bà yìí ni a máa pín sí orí márùn-ún ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ kí iṣẹ́ náà máà ba kọlu ara wọn, kí ìdàrúdàpọ̀ máà ba wà, kí àwọn àlàyè wá sì lè yéni yékéyéké.
Bẹ̀rẹ̀ láti orí kìn-ín-ní iṣẹ́ ìwádìí yìí ni a ti kọ́kọ́ ṣe ìfáàrà sí iṣẹ́ ìwádìí yìí kí a lè ní ìmọ̀ nípa ohun tí iṣẹ́ ìwádìí yìí dálé lórí, kí òye ohun tí a fẹ́ ṣiṣẹ́ lé lórí sì le yé wa dáadáa. Lẹ́yìn ìfáàrà ni a wo èròńgbà wa tí í ṣe ìdí tí a fi yan iṣẹ́ yìí láàyò gan-an. Bákan náà ni a wá wo ibí tí iṣẹ́ ìwádìí náà yóò fẹjú dé, tí a ti ṣe àlàkalẹ̀ lórí àwọn ohun tí a máa mẹ́nu bà ni orí kọ̀ọ̀kan tí iṣẹ́ náà yóò fi parí. Orí kìn-ín-ní yìí náà ni a ti wo irú ọgbọ́n ìwádìí tí a múlò láti mú kí iṣẹ́ ìwádìí náà kẹ́sẹ jarí, tí a sì wo àwọn ìṣòro tí a dojú kọ lọ́nà àti ṣe iṣẹ́ ìwádìí náà tí a sì kásẹ̀ orí kìn-ín-ní náà nílẹ̀ pẹ̀lú àǹfààní tí iṣẹ́ ìwádìí náà yóò mú jáde.
Orí kejì iṣẹ́ ìwádìí yìí, ni a ó ti ṣe àgbéyẹ̀wò iṣẹ́ àtẹ̀yìnwá léte àti mọ ibi tí iṣẹ́ dé dúró lórí ọdún ìbílẹ̀. A ó sọ ìtàn ìlú Ìjàrẹ́, ìyẹn ìtàn nípa bí ìlú Ìjàrẹ́ ṣe ṣẹ̀ wá láti wá tẹ̀dó sí ibi tí wọ́n wà lónìí yìí àti pàápàá jùlọ bí wọ́n ṣe gba orúkọ. Lábẹ́ orí yìí, ni a ti máa sọ oríkì ìlú yìí, a ó wo iye àwọn ọba tí ó ti jẹ ní ìlú náà láti ìgbà ìwásẹ̀ àti iye ọdún tí àwọn ọba náà fi jẹ fún ara wọn tí àkọsílẹ̀ bá wà fún èyí. A máa wo iye àdúgbò tó bá wà ní ìlú yìí, àti àwọn ọdún ìbílẹ̀ mìíràn tàbí àwọn òrìṣà tí wọ́n ń bọ. Bákan náà ni a ó wo bí ètò ẹ̀sìn, ètò ìṣèlú, àti ètò ọrọ̀ ajé ìlú yìí ṣe rí àti àwọn iṣẹ́ tí àwọn ènìyàn ìlú yìí ń ṣe. Gbogbo nǹkan wọ̀nyí ni a máa gbéyẹ̀wò kí a tó kásẹ̀ orí náà nílẹ̀.
Ní orí kẹta gan-an ni a ti máa wá ṣe òríkinníwìn àlàyé lórí ọdún Ọlọ́fin gan-an, a ó wo irúfẹ́ ọdún tí ọdún yìí jẹ́, ní pàtó, bí wọ́n ṣe ń ṣe ọdún náà, ìgbà tí wọ́n máa ń ṣe ọdún náà, àwọn tó lẹ́tọ̀ọ́ láti kópa, ipa tí ọba àti àwọn aráàlú máa ń kó nínú ọdún náà, àwọn èèwọ̀ tó rọ̀ mọ́ ṣíṣe ọdún náà àti irú ìjìyà tó tọ́ sí ẹnikẹ́ni tó bá dẹ́jàá àwọn èèwọ̀ náà àti àwọn nǹkan mìíràn tó bá yẹ kí a mẹ́nu bà nínú ọdún náà.
Ní orí kẹrin ni a ti máa wa wo àwọn àyípadà tó ti dé bá ṣíṣe ọdún Ọlọ́fin yìí, ó sì di dandan kí á wo àwọn ohun tó ṣokùnfa àwọn àyípadà náà. A sì máa wo ipa tí ọdún Ọlọ́fin yìí ń kó láàárín ìlú àti ìgbàgbọ́ àwọn ará ìlú Ìjàrẹ́ nípa ṣíṣe ọdún Ọlọ́fin yìí. A ó sì wo àwọn àǹfààní tí ọdún Ọlọ́fin yìí ń mú bá ìlú láti fi kásẹ̀ orí kẹrin náà nílẹ̀.
Ní orí karùn-ún ni a ti máa wa ọkọ̀ wa gúnlẹ̀ lórí iṣẹ́ ìwádìí yìí, níbi tí a ó ti máa ṣe ìsọníṣókí gbogbo ohun tí à ń bábọ̀ látẹ̀yín wá, láti lè pe àkíyèsí wa sí àwọn ohun tí a ti sọ̀rọ̀ lé lórí nínú iṣẹ́ náà. bákan náà ni a ó sọ àwọn àríwísí tiwa lórí iṣẹ́ náà, ìyẹn àwọn ohun tí a ṣe àkíyèsí pé ó kù díẹ̀ káàtó nípa ṣíṣe ọdún náà tí a sì máa sọ ìmọ̀ràn ti wa fún ọjọ́ ọ̀la ọdún Ọlọ́fin ní ìlú Ìjàrẹ́.
1.3 ỌGBỌ́N ÎWÁDÌÍ
Nínú irú iṣẹ́ ìwádìí báyìí, kò sí bí a ti lè jẹ́ ọlọ́gbọ́n tó tàbí ọ̀mọ̀ràn tó tí a lè ṣe irú iṣẹ́ báyìí pẹ̀lú ọpọlọ tiwa nìkan, nítorí irú iṣẹ́ báyìí máa ń nílò àwọn àgbààgbà tí ọjọ́ orí wọn ti tó ogójì ọdún sókè, tó jẹ́ ọmọ ìlú Ìjàrẹ́ tó sì gbélé dáadáa láti fi ọ̀rọ̀ wá lẹ́nu wò, nítorí irú àwọn ènìyàn báyìí ni a ní ìgbàgbọ́ pé, wọ́n le mọ tìfun tẹ̀dọ̀ gbogbo ohun tí a máa béèrè, yálà nípa ìlú tàbí nípa ọdún tí à ń ṣiṣẹ́ lé lórí gan-an. Ìdí nìyí tí a ṣe kọ́kọ́ digbá dẹrù wa tí a fi mú ọ̀nà ìlú Ìjàrẹ́ pọ̀n láti lọ ṣe ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò pẹ̀lú àwọn abẹ̀nà ìmọ̀ láti gba dẹ́tà nípa àwọn ohun tí a fẹ́ sọ̀rọ̀ lé lórí lọ́wọ́ wọn. Èyí ni ọgbọ́n àkọ́kọ́ tí a múlò tó sì lànà iṣẹ́ náà fún wa. Ẹ̀yìn èyí ni a gbá yàrá ìyáwèékàwé lọ láti lọ yẹ àwọn ìwé onímọ̀ wò tí wọ́n ti sọ̀rọ̀ lórí àwọn ọ̀kan-ò-jọ̀kàn ọdún ìbílẹ̀ àti àwọn iṣẹ́ àpilẹ̀kọ tó ti wà nílẹ̀ lórí ọdún ìbílẹ̀ tí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tó ti kọjá ti ṣiṣẹ́ ìwádìí lé lórí.
A sì tún ṣe àmúlò ọgbọ́n àti ìtọ́nisọ́nà tí alábòójútó iṣẹ́ yìí fún wa ní gbogbo ìgbà tí a fi ń ṣe iṣẹ́ yìí tí a sì ń bù wọ́n gbọ́ nípa bó ṣe ń lọ. Èyí sì ràn wá lọ́wọ́ gidigidi nítorí ó jẹ́ kí a mọ bí a ṣe máa ṣe àgbékalẹ̀ iṣẹ́ yìí àti àwọn ohun tí ó yẹ kí a mẹ́nu bà nípa iṣẹ́ náà. a sì tún bẹ àwọn aṣáájú wa wò tí wọ́n tí ṣe iṣẹ́ báyìí fúnra wọn rí láti lè fi ìmọ̀ tiwọn tí wọ́n lò fi ṣe iṣẹ́ wọn ní àṣeyọrí kún tiwa. Ìwọ̀nyí ni àwọn ọgbọ́n àti ète tí a múlò kí a tó lè kẹsẹ́járí nínú iṣẹ́ ìwádìí yìí.
Full-Text Access Notice
In accordance with the NERD Policy on promoting peer-reviewed publication, public access to the full text of a project, thesis or dissertation is restricted for three years, allowing the author and supervisors sufficient time to pursue peer-reviewed publication.
During this period, researchers with legitimate academic or research purposes may request authorisation directly from the author to enable NERD to release the indexed full texts of the work using the form below.